Amosi 9:1-6
1
Mo rí Olúwa, ó dúró ní ẹ̀bá pẹpẹ, ó sì wí pé: “Lu orí àwọn àtẹ́rígbà ìlẹ̀kùn kí àwọn òpó kí ó lè mì fọ́ wọn sí orí àwọn gbogbo ènìyàn àwọn tí ó ṣẹ́kù ni èmi yóò fi idà pa, ẹni tí ó sálọ nínú wọn kí yóò sá gbé, ẹni ti ó sá àsálà nínú wọn kí yóò gbàlà.
2
Bí wọ́n tilẹ̀ wa ilẹ̀ lọ sí ipò òkú, láti ibẹ̀ ni ọwọ́ mi yóò ti tẹ̀ wọ́n. Bí wọ́n tilẹ̀ gun òkè ọ̀run lọ, láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti mú wọn sọ̀kalẹ̀.
3
Bí wọ́n tilẹ̀ fi ara wọn pamọ́ ni orí òkè Karmeli, èmi yóò wá wọn rí, Èmi yóò si mú wọn kúrò níbẹ̀. Bí wọ́n tilẹ̀ fi ara pamọ́ fún mi sí ìsàlẹ̀ Òkun, láti ibẹ̀ ni Èmi yóò ti pàṣẹ fún ejò kí ó bù wọ́n ṣán.
4
Bí wọ́n tilẹ̀ lọ sí ìgbèkùn ní iwájú àwọn ọ̀tá wọn láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti pàṣẹ fún idà kí ó ṣá wọn pa. “Èmi yóò sì tẹ ojú mi mọ́ wọn fún ìbí, kì í sì í ṣe fún rere.”
5
Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ẹni ti ó fi ọwọ́ kan ilẹ̀ náà tí ó sì yọ́, tí àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò sì ṣọ̀fọ̀; gbogbo orílẹ̀-èdè yóò si ru sókè bí ríru odò Naili tiwọn yóò sì tẹ̀rì bí odò Ejibiti.
6
Òun ni ẹni tí ó kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ nínú àwọn ọ̀run ti ó sì fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ ní ilé ayé, Ẹni ti ó pe àwọn omi Òkun ti ó sì tú wọn jáde si orí ilé ayé Olúwa ni orúkọ rẹ̀.
Settings