Amosi 8:11-14
11
“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa Olódùmarè wí, “nígbà tí èmi yóò rán ìyàn sí ilẹ̀ náà, kì í ṣe ìyàn oúnjẹ tàbí òǹgbẹ fún omi. Ṣùgbọ́n ìyàn gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.
12
Àwọn ènìyàn yóò rìn kiri láti Òkun dé Òkun wọn yóò sì máa rìn ká láti gúúsù sí àríwá, wọn yóò máa wá ọ̀rọ̀ Olúwa ṣùgbọ́n wọn kì yóò rí i.
13
“Ní ọjọ́ náà “àwọn arẹwà wúńdíá àti àwọn alágbára ọ̀dọ́mọkùnrin yóò dákú fún òǹgbẹ omi.
14
Àwọn tí ó fi ẹ̀ṣẹ̀ Samaria búra, tí wọ́n sì wí pé, ‘Bí ó ti dájú pé ọlọ́run rẹ ń bẹ láààyè, ìwọ Dani,’ bí ó ti dájú pè ọlọ́run rẹ ń bẹ láààyè, ìwọ Beerṣeba, wọ́n yóò ṣubú, wọn kì yóò si tún dìde mọ.”
Settings