Ìṣe àwọn Aposteli 23:16-22
16
Nígbà tí ọmọ arábìnrin Paulu sí gbúròó ìdìtẹ̀ wọn, ó lọ, ó sì wọ inú àgọ́ àwọn ológun lọ, ó sì sọ fún Paulu.
17
Paulu sì pé ọ̀kan nínú àwọn balógun ọ̀run sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Mú ọmọkùnrin yìí tọ olórí ogun lọ, nítorí ó ní nǹkan láti sọ fún un.”
18
Ó mú un, ó sì sìn ín lọ sọ́dọ̀ olórí ogun. Balógun ọ̀rún náà wí pé, “Paulu òǹdè pè mi sọ́dọ̀ rẹ̀, ó síbẹ̀ mí pé ki èmi mú ọmọkùnrin yìí tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ó ní nǹkan láti sọ fún ọ.”
19
Alábojútó-ogun fà á lọ́wọ́, ó sì lọ si apá kan, ó sì bi í léèrè níkọ̀kọ̀ pé, “Kín ni ohun tí ìwọ ní sọ fún mi?”
20
Ó sì wí pé, “Àwọn Júù fi ìmọ̀ ṣọ̀kan láti wá bẹ̀ ọ́, kí o mú Paulu sọ̀kalẹ̀ wá sí àjọ ìgbìmọ̀ ní ọ̀la, bí ẹni pé àwọn ń fẹ́ béèrè nǹkan dájúdájú nípa rẹ̀.
21
Nítorí náà má ṣe gbọ́ tiwọn, nítorí àwọn tí ó dènà dè é nínú wọn ju ogójì ọkùnrin lọ, tí wọ́n fi ara wọn bú pé, àwọn kì yóò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kì yóò mu títí àwọn o fi pa á. Wọ́n sì ti múra tan nísinsin yìí, wọ́n ń retí ìdáhùn lọ́dọ̀ rẹ.”
22
Nígbà náà ni olórí ogun fi ọmọ náà sílẹ̀ láti lọ, ó sí kìlọ̀ fún un pé, “Má ṣe wí fún ẹnìkan pé, ìwọ fi nǹkan wọ̀nyí hàn mi.”
Settings