Skip to content
2 Samuẹli 22:17-30

2 Samuẹli 22:17-30

17
“Ó ránṣẹ́ láti òkè wá, ó mú mi; ó fà mí jáde láti inú omi ńlá wá.
18
Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára, lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi, nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ.
19
Wọ́n wá láti borí mi lọ́jọ́ ìpọ́njú mi, ṣùgbọ́n Olúwa ni aláfẹ̀yìntì mi.
20
Ó sì mú mi wá sí ààyè ńlá, ó gbà mi, nítorí tí inú rẹ̀ dún sí mi.
21
“Olúwa sán án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi; ó sì san án fún mi gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi.
22
Nítorí pé èmi pa ọ̀nà Olúwa mọ́, èmi kò sì fi ìwà búburú yapa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi.
23
Nítorí pé gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ ni ó wà níwájú mi; àti ní ti òfin rẹ̀, èmi kò sì yapa kúrò nínú wọn.
24
Èmi sì wà nínú ìwà títọ́ sí í, èmi sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi.
25
Olúwa sì san fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi, gẹ́gẹ́ bí ìwà mímọ́ mi níwájú rẹ̀.
26
“Fún aláàánú ni ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ni aláàánú, àti fún ẹni ìdúró ṣinṣin ní òdodo ni ìwọ ó fi ara rẹ hàn ní ìdúró ṣinṣin ní òdodo.
27
Fún onínú funfun ni ìwọ fi ara rẹ hàn ní funfun; àti fún ẹni wíwọ́ ni ìwọ ó fi ara rẹ hàn ní wíwọ́.
28
Àwọn ènìyàn tí ó wà nínú ìyà ni ìwọ ó sì gbàlà; ṣùgbọ́n ojú rẹ wà lára àwọn agbéraga, láti rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.
29
Nítorí ìwọ ni ìmọ́lẹ̀ mi, Olúwa; Olúwa yóò sì sọ òkùnkùn mi di ìmọ́lẹ̀.
30
Bẹ́ẹ̀ ni nítorí nípa rẹ̀ ni èmi ti la àárín ogun kọjá; nípa Ọlọ́run mi èmi ti fo odi kan.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options