2 Ọba 8:1
Ń ṣàfihàn ẹsẹ 1 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
1
Nísinsin yìí, Eliṣa wí fún obìnrin náà tí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin jí padà sáyé pé, “Jáde lọ pẹ̀lú ìdílé rẹ kí o sì lọ dúró fún ìgbà díẹ̀ ní ibikíbi tí o bá le dúró sí, nítorí Olúwa ti pàṣẹ ìyàn ní ìlú tí yóò lò tó ọdún méje.”
2
Obìnrin náà tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ènìyàn Ọlọ́run ti sọ. Òun àti ìdílé rẹ̀ sí lọ, wọ́n sì ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àwọn ará Filistini fún ọdún méje.
3
Ní ẹ̀yìn ọdún méje ó sì padà wá láti ilẹ̀ àwọn ará Filistini ó sì lọ sí ọ̀dọ̀ ọba láti lọ bẹ̀ ẹ́ fún ilé àti ilẹ̀ rẹ̀.
4
Ọba sì ń sọ̀rọ̀ sí Gehasi, ìránṣẹ́ ènìyàn Ọlọ́run pé, “Sọ fún mi nípa gbogbo ohun ńlá tí Eliṣa ti ṣe.”
Settings