Skip to content
2 Ọba 7:3-8

2 Ọba 7:3-8

3
Nísinsin yìí àwọn ọkùnrin mẹ́rin kan wà pẹ̀lú ẹ̀tẹ̀ ní ẹnu àbáwọlé ibodè ìlú. Wọ́n wí fún olúkúlùkù pé, “Kí ni ó dé tí àwa yóò fi jókòó síbí títí àwa yóò fi kú?
4
Tí àwa bá wí pé, ‘Àwa lọ sí ìlú, ìyàn wà níbẹ̀,’ àwa yóò sì kú. Tí àwa bá dúró níbí, a máa kú, ǹjẹ́ nísinsin yìí ẹ jẹ́ kí a lọ sí ibùdó ti àwọn ará Siria kí àwa kí ó sì tẹríba. Bí wọ́n bá dá wa sí, àwa yóò yè, tí wọ́n bá sì pa wá, bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò kú.”
5
Ní àfẹ̀mọ́júmọ́ wọ́n dìde wọ́n sì lọ sí ibùdó àwọn ará Siria. Nígbà tí wọ́n dé ẹ̀gbẹ́ ibùdó náà, kò sí ọkùnrin kan níbẹ̀,
6
nítorí tí Olúwa jẹ́ kí àwọn ará Siria gbọ́ ìró kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin àti ogun ńlá, wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Ẹ wò ó, ọba Israẹli ti bẹ ogun àwọn Hiti àti àwọn ọba Ejibiti láti dojúkọ wá!”
7
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì dìde wọ́n sì sálọ ní àfẹ̀mọ́júmọ́ wọ́n sì fi àgọ́ wọn sílẹ̀ àti ẹṣin wọn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Wọ́n sì fi ibùdó sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti wà, wọ́n sì sálọ fún ẹ̀mí wọn.
8
Nígbà tí àwọn ọkùnrin tí ó ní ààrùn ẹ̀tẹ̀ dé ẹ̀gbẹ́ ibùdó wọ́n sì wọ inú ọ̀kan nínú àgọ́ náà. Wọ́n jẹ wọ́n sì mu, wọ́n sì kó fàdákà, wúrà àti ẹ̀wù, wọ́n sì lọ. Wọ́n sì wọ àgọ́ mìíràn lọ, wọ́n kó àwọn nǹkan láti ibẹ̀ wọ́n sì kó wọn pamọ́ pẹ̀lú.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options