2 Ọba 13:1-8
1
Ní ọdún kẹtàlélógún ti Joaṣi ọmọ ọba Ahasiah ti Juda, Jehoahasi ọmọ Jehu di ọba Israẹli ní Samaria. Ó sì jẹ ọba fún ọdún mẹ́tàdínlógún.
2
Ó ṣe búburú níwájú Olúwa nípa títẹ̀lé ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá, kò sì yípadà kúrò nínú wọn.
3
Bẹ́ẹ̀ ni ìbínú Olúwa ru sí àwọn ọmọ Israẹli, àti fún ìgbà pípẹ́, ó fi wọ́n pamọ́ sí abẹ́ agbára ọba Hasaeli ọba Siria àti Beni-Hadadi ọmọ rẹ̀.
4
Nígbà náà Jehoahasi kígbe ó wá ojúrere Olúwa, Olúwa sì tẹ́tí sí i. Nítorí ó rí bí ọba Siria ti ń ni Israẹli lára gidigidi.
5
Olúwa pèsè olùgbàlà fún Israẹli, wọ́n sì sá kúrò lọ́wọ́ agbára Siria. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli gbé nínú ilé ara wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti wà tẹ́lẹ̀.
6
Ṣùgbọ́n wọn kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ ilé Jeroboamu, èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá, wọ́n tẹ̀síwájú nínú rẹ̀, ère òrìṣà Aṣerah sì wà síbẹ̀ ní Samaria pẹ̀lú.
7
Kò sí ohùn kan tí wọ́n fi sílẹ̀ ní ti ọmọ-ogun Jehoahasi àyàfi àádọ́ta ọkùnrin ẹlẹ́ṣin, kẹ̀kẹ́ mẹ́wàá, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọmọ-ogun ẹlẹ́ṣẹ̀, nítorí ọba Siria ti pa ìyókù run, ó sì ṣe wọ́n bí eruku nígbà pípa ọkà.
8
Fún ti ìyókù ìṣe Jehoahasi fún ìgbà, tí ó fi jẹ ọba, gbogbo ohun tí ó ṣe àti àṣeyọrí rẹ̀ ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli?
Settings