2 Kọrinti 1:8-9
8
Arákùnrin àti arábìnrin, àwa kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè nípa wàhálà tí ó dé bá wa ní agbègbè Asia, ní ti pé a pọ́n wa lójú gidigidi rékọjá agbára ìfaradà wa, tó bẹ́ẹ̀ tí ìrètí kò tilẹ̀ sí fún ẹ̀mí wa mọ́.
9
Nítòótọ́, nínú ọkàn wa a tilẹ̀ ní ìmọ̀lára wí pé a tí gba ìdálẹ́bi ikú, ṣùgbọ́n èyí farahàn láti má mú wa gbẹ́kẹ̀lé ara wa bí kò ṣe Ọlọ́run tí ń jí òkú dìde.
Settings