2 Kronika 6:4-11
4
Nígbà náà ni ó sì wí pé: “Ògo ni fún Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ mú ohun tí ó fi ẹnu rẹ̀ sọ fún Dafidi baba mi ṣẹ. Nítorí tí ó wí pé,
5
‘Láti ọjọ́ tí èmi ti mú àwọn ènìyàn mi jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, èmi kò yan ìlú kan nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli, láti kọ́ ilé, kí orúkọ mi kí ó lè wà níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò yan ẹnikẹ́ni láti jẹ́ olórí lórí Israẹli ènìyàn mi.
6
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi ti yan Jerusalẹmu, kí orúkọ mi le è wà níbẹ̀, èmi sì ti yan Dafidi láti jẹ ọba lórí Israẹli ènìyàn mi.’
7
“Baba mi Dafidi ti ní-in lọ́kàn láti kọ́ tẹmpili fún orúkọ Olúwa, àní Ọlọ́run Israẹli.
8
Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Dafidi baba mi pé, ‘Nítorí tí ó wà ní ọkàn rẹ láti kọ́ tẹmpili yìí fún orúkọ mi, ìwọ ṣe ohun dáradára láti ní èyí ní ọkàn rẹ̀.
9
Ṣùgbọ́n síbẹ̀, ìwọ kọ́ ni yóò kọ́ tẹmpili náà, bí kò ṣe ọmọ rẹ, ẹni tí o jẹ́ ẹran-ara àti ẹ̀jẹ̀ rẹ: òun ni yóò kọ́ tẹmpili fún orúkọ mi.’
10
“Olúwa sì ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Èmi ti dìde ní ipò Dafidi baba mi, a sì gbé mi ka ìtẹ́ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ṣe ìlérí, èmi sì ti kọ́ tẹmpili fún orúkọ Olúwa, Ọlọ́run Israẹli.
11
Níbẹ̀ ni èmi sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa sí, nínú èyí ti májẹ̀mú ti Olúwa bá àwọn Israẹli ènìyàn mi dá wà.”
Settings