2 Kronika 35:1-3
1
Síwájú sí i, Josiah ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá sí Olúwa ní Jerusalẹmu, Ọ̀dọ́-àgùntàn àjọ ìrékọjá náà ni wọ́n sì pa ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní.
2
Ó sì yàn àwọn àlùfáà sí iṣẹ́ wọn, ó sì gbà wọ́n ní ìyànjú ní ìsìn ilé Olúwa.
3
Ó sì wí fún àwọn ọmọ Lefi, ẹni tí ń kọ́ gbogbo àwọn Israẹli ẹni tí a ti yà sí mímọ́ fún Olúwa pé ẹ gbé àpótí ẹ̀rí ìyàsọ́tọ̀ sí ilé Olúwa tí Solomoni ọmọ Dafidi ọba Israẹli ti kọ́. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹrù àgbéká ní èjìká rẹ̀. Nísinsin yìí ẹ sin Olúwa Ọlọ́run yín àti àwọn ènìyàn rẹ̀ Israẹli.
Settings