2 Kronika 34:8
Ń ṣàfihàn ẹsẹ 8 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
5
Ó sì sun àwọn egungun àwọn àlùfáà lórí pẹpẹ wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni ó sì wẹ Juda àti Jerusalẹmu mọ́.
6
Ní ìlú Manase, Efraimu àti Simeoni, àní títí ó fi dé Naftali, àti nínú àwọn, ó tú ilé wọn yíkákiri.
7
Ó sì wó pẹpẹ àti ère Aṣerah lulẹ̀ àti àwọn ère yíyá àti àwọn òrìṣà, ó sì gùn ó sì ti ké gbogbo àwọn ère orí pẹpẹ lulẹ̀ ní gbogbo àyíká Israẹli. Lẹ́yìn náà ó padà sí Jerusalẹmu.
8
Ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Josiah ni a ti wẹ ilẹ̀ náà mọ́ àti ilé Olúwa, ó sì rán Ṣafani ọmọ Asalia àti Maaseiah olórí ìlú náà, pẹ̀lú Joah, ọmọ Joahasi, akọ̀wé, láti tún ilé Olúwa Ọlọ́run ṣe.
9
Wọ́n sì lọ sí ọ̀dọ̀ Hilkiah olórí àlùfáà, ó sì fún un ní owó náà tí ó mú wá sí inú ilé Ọlọ́run, ti àwọn ọmọ Lefi ẹni tí ó jẹ́ aṣọ́bodè ti gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn Manase Efraimu àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ìyókù Israẹli àti ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn Juda àti Benjamini wọ́n sì padà sí Jerusalẹmu.
10
Nígbà náà ni wọn sì fi le àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ilé lọ́wọ́, àwọn tí ń ṣe alábojútó iṣẹ́ ilé Olúwa. Àwọn ọkùnrin yìí sì san owó fún àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ń túnṣe, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ ní ilé Olúwa.
11
Wọ́n sì tún fi owó fún àwọn oníṣọ̀nà àti àwọn olùkọ́lé láti ra òkúta gbígbẹ́ àti ìtì igi fún ìsopọ̀ àti igi rírẹ́ fún ìkọ́lé tí ọba Juda ti gbà láti túnṣe.
Settings