Skip to content
2 Kronika 33:6-13

2 Kronika 33:6-13

6
Ó sì mú kí àwọn ọmọ ara rẹ̀ kí ó kọjá láàrín iná ní àfonífojì Beni-Hinnomu, ó ń ṣe àkíyèsí àfọ̀ṣẹ, ó sì ń lo àlúpàyídà, ó sì ń bá àwọn òku àti oṣó lò. Ó ṣe ọ̀pọ̀ ohun búburú ní ojú Olúwa láti mú un bínú.
7
Ó mú ère gbígbẹ́ tí ó ti gbẹ́ ó sì gbé e sínú ilé Olúwa, ní èyí tí Ọlọ́run ti sọ fún Dafidi àti sí ọmọ rẹ̀ Solomoni, “Nínú ilé Olúwa yìí àti ní Jerusalẹmu, tí mo ti yàn kúrò nínú gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli, èmi yóò fi orúkọ mi síbẹ̀ títí láé.
8
Èmi kì yóò ṣí ẹsẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli kúrò mọ́ ní ilẹ̀ náà tí èmi ti yàn fún àwọn baba ńlá yín, níwọ̀n bí wọ́n bá ṣe pẹ̀lẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tí mo paláṣẹ fún wọn, gẹ́gẹ́ bí gbogbo òfin, àṣẹ àti àwọn ìlànà tí a fún yín láti ọwọ́ Mose wá.”
9
Ṣùgbọ́n Manase mú kí Juda àti àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu yapa, àti láti ṣe búburú ju àwọn orílẹ̀-èdè lọ, àwọn tí Olúwa ti parun níwájú àwọn ọmọ Israẹli.
10
Olúwa bá Manase sọ̀rọ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò kọbi ara sí i.
11
Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa mú àwọn alákòóso ọmọ-ogun ọba Asiria láti dojúkọ wọ́n, tí ó mú Manase nígbèkùn, ó fi ìwọ̀ mú un ní imú rẹ̀, ó dè é pẹ̀lú ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ idẹ ó sì mú un lọ sí Babeli.
12
Nínú ìpọ́njú rẹ̀, ó wá ojúrere Olúwa Ọlọ́run rẹ̀. Ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gidigidi níwájú Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀.
13
Nígbà tí ó sì gbàdúrà sí i, inú Olúwa dùn sí àdúrà rẹ̀, ó sì tẹ́tí sí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni ó mú un padà wá sí Jerusalẹmu àti sí ìjọba rẹ̀. Nígbà náà Manase mọ̀ wí pé Olúwa ni Ọlọ́run.
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options