Skip to content
2 Kronika 17:10-19

2 Kronika 17:10-19

10
Ìbẹ̀rù Olúwa bà lórí gbogbo ìjọba ilẹ̀ tí ó yí Juda ká, dé bi pé wọn kò bá Jehoṣafati jagun.
11
Lára àwọn ará Filistini, mú ẹ̀bùn fàdákà gẹ́gẹ́ bí owó ọba wá fún Jehoṣafati, àwọn ará Arabia sì mú ọ̀wọ́ ẹran wá fún un, ẹgbàarindín ní ọ̀ọ́dúnrún (7,700) àgbò àti ẹgbàarindín ní ọ̀ọ́dúnrún (7,700) òbúkọ.
12
Jehoṣafati sì ń di alágbára nínú agbára sí i, ó sì kọ́ ilé olódi àti ilé ìṣúra púpọ̀ ní Juda
13
Ó sì ní ìṣúra ní ìlú Juda. Ó sì tún ní àwọn alágbára jagunjagun akọni ọkùnrin ní Jerusalẹmu.
14
Iye wọn gẹ́gẹ́ bí ilé baba wọn nìwọ̀nyí. Láti Juda, àwọn olórí ìpín kan ti ẹgbẹ̀rún (1,000): Adina olórí, pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (300,000) alágbára akọni ọkùnrin.
15
Èkejì, Jehohanani olórí, pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá (280,000) ọkùnrin;
16
àtẹ̀lé Amasiah ọmọ Sikri, ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún iṣẹ́ Olúwa pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000).
17
Láti ọ̀dọ̀ Benjamini: Eliada, alágbára akọni ọkùnrin pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000) àwọn jagunjagun ọkùnrin pẹ̀lú ọrun àti àpáta ìhámọ́ra;
18
àtẹ̀lé Jehosabadi, pẹ̀lú ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án (180,000) jagunjagun ọkùnrin múra sílẹ̀ fún ogun.
19
Wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ń dúró níwájú ọba, ní àyíká àwọn ẹni tí ó fi sínú ìlú olódi ní àyíká gbogbo Juda.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options