17
Ó fún ìjọba Juda ní agbára, ó sì ti Rehoboamu ọmọ Solomoni lẹ́yìn fún ọdún mẹ́ta nítorí ọdún mẹ́ta ni wọ́n fi rìn ní ọ̀nà ti Dafidi àti Solomoni ní àkókò yí.
18
Rehoboamu fẹ́ Mahalati tí ó jẹ́ ọmọbìnrin ti ọmọkùnrin Dafidi Jerimoti bi àti ti Abihaili, ọmọbìnrin ti ọmọkùnrin Jese Eliabu bí.