1 Tẹsalonika 2:13-16
13
Àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà nítorí pé, ẹ kò ka ọ̀rọ̀ ìwàásù wa sí ọ̀rọ̀ ti ara wa. Pẹ̀lú ayọ̀ ni ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a wí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, òtítọ́ sì ni pé, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni, èyí tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́.
14
Nítorí, ẹ̀yin ara, ẹ jẹ́ àwòkọ́ṣe àwọn ìjọ Ọlọ́run tí o wà ní Judea nínú Kristi Jesu. Nítorí pé ẹ̀yin pẹ̀lú jìyà irú ohun kan náà lọ́wọ́ àwọn ará ìlú yín, gẹ́gẹ́ bí àwọn pẹ̀lú ti jìyà lọ́wọ́ àwọn Júù,
15
àwọn tí wọ́n pa Jesu Olúwa àti àwọn wòlíì, tí wọ́n sì tì wa jáde. Wọn kò ṣe èyí tí ó wu Ọlọ́run, wọ́n sì ṣe lòdì sí gbogbo ènìyàn
16
nínú ìgbìyànjú wọn láti dá ìwàásù ìyìnrere dúró láàrín àwọn aláìkọlà kí wọn kí ó lè rí gbàlà. Ẹ̀ṣẹ̀ wọn ń di púpọ̀ sí i lójoojúmọ́. Ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn, ìbínú Ọlọ́run ti wá sórí wọn ní ìgbẹ̀yìn.
Settings