Skip to content
1 Ọba 21:17

1 Ọba 21:17

Ń ṣàfihàn ẹsẹ 17 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
14
Nígbà náà ni wọ́n ránṣẹ́ sí Jesebeli wí pé, “A ti sọ Naboti ní òkúta, ó sì kú.”
15
Bí Jesebeli sì ti gbọ́ pé, a ti sọ Naboti ní Òkúta pa, ó sì wí fún Ahabu pé, “Dìde! Kí o sì jogún ọgbà àjàrà Naboti, ará Jesreeli, tí ó kọ̀ láti tà fún ọ kò sí láààyè mọ́, ó ti kú.”
16
Nígbà tí Ahabu sì gbọ́ pé Naboti ti kú, ó sì dìde, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ láti jogún ọgbà àjàrà Naboti.
17
Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Elijah ará Tiṣibi wá wí pé,
18
“Sọ̀kalẹ̀ lọ láti lọ pàdé Ahabu ọba Israẹli, tí ó wà ní Samaria. Ó wà ní ọgbà àjàrà Naboti báyìí, níbi tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ láti jogún rẹ̀.
19
Sọ fún un pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Ǹjẹ́ ìwọ kò ti pa ènìyàn, o sì ti fi agbára gba ogún rẹ̀?’ Nígbà náà ni kí o wí fún un pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Níbi tí ajá gbé lá ẹ̀jẹ̀ Naboti, ni àwọn ajá yóò lá ẹ̀jẹ̀ rẹ, àní tìrẹ!’ ”
20
Ahabu sì wí fún Elijah pé, “Ìwọ ti rí mi, ìwọ ọ̀tá mi!” Ó sì dáhùn wí pé, “Èmi ti rí ọ, nítorí tí ìwọ ti tan ara rẹ láti ṣe búburú níwájú Olúwa.
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options