Skip to content
1 Ọba 20:31-34

1 Ọba 20:31-34

31
Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí fún un pé, “Wò ó, a ti gbọ́ pé àwọn ọba ilẹ̀ Israẹli jẹ́ ọba aláàánú, mo bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí àwa kí ó tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú aṣọ ọ̀fọ̀ ní ẹ̀gbẹ́ wa, àti okùn yí orí wa ká. Bóyá òun yóò gba ẹ̀mí rẹ là.”
32
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n di aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ wọn, wọ́n sì fi okùn yí orí wọn ká, wọ́n sì tọ ọba Israẹli wá, wọ́n sì wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ Beni-Hadadi wí pé, ‘Èmi bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí èmi kí ó yè.’ ” Ọba sì dáhùn wí pé, “Ó ń bẹ láààyè bí? Arákùnrin mi ni òun.”
33
Àwọn ọkùnrin náà sì ṣe àkíyèsí gidigidi, wọ́n sì yára gbá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú, wọ́n sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Beni-Hadadi arákùnrin rẹ.” Ọba sì wí pé, “Ẹ lọ mú u wá.” Nígbà tí Beni-Hadadi jáde tọ̀ ọ́ wá, Ahabu sì mú u gòkè wá sínú kẹ̀kẹ́.
34
Beni-Hadadi sì wí pé, “Èmi yóò dá àwọn ìlú tí baba mi ti gbà lọ́wọ́ baba rẹ padà, ìwọ sì le la ọ̀nà fún ara rẹ ní Damasku, bí baba mi ti ṣe ní Samaria.” Ahabu sì wí pé, “Èmi yóò rán ọ lọ pẹ̀lú májẹ̀mú yìí.” Bẹ́ẹ̀ ni ó ba dá májẹ̀mú, ó sì rán an lọ.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options