Skip to content
1 Kronika 9:17-32

1 Kronika 9:17-32

17
Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà: Ṣallumu, Akkubu, Talmoni, Ahimani àti arákùnrin wọn, Ṣalumu olóyè wọn,
18
ti wà ní ipò ìdúró ní ẹnu-ọ̀nà ọba ní apá ìhà ìlà-oòrùn títí di àkókò yí. Wọ̀nyí ni àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà tí ó jẹ́ ti ìpàgọ́ àwọn ará Lefi.
19
Ṣallumu ọmọ Kore ọmọ Ebiasafi, ọmọ Kora, àti àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Láti ìdílé rẹ̀ (àwọn ará Korati) ni ó dúró fún ṣíṣọ́ ìloro ẹnu-ọ̀nà àgọ́ gẹ́gẹ́ bí baba wọn ti ń dúró fún ṣíṣọ́ àbáwọlé ibùgbé Olúwa.
20
Ní ìgbà àkọ́kọ́ Finehasi ọmọ Eleasari jẹ́ olórí fún àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà, Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀.
21
Sekariah, ọmọ Meṣelemiah jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ní àbáwọlé sí àgọ́ ibi ìpàdé.
22
Gbogbo rẹ̀ lápapọ̀, àwọn tí a yàn láti jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ní àwọn ìloro jẹ́ igba ó lé méjìlá (212). A ka àwọn wọ̀nyí nípa ìdílé ní ìletò wọn. Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ni a ti yàn sí ipò láti ọ̀dọ̀ Dafidi àti Samuẹli, aríran, nítorí òtítọ́ wọn.
23
Àwọn àti àwọn ọmọ wọn ni ó wà fún ṣíṣọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa ilé tí a pè ní àgọ́.
24
Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà wà ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin: ìlà-oòrùn, ìwọ̀-oòrùn àríwá àti gúúsù.
25
Àwọn arákùnrin wọn ní àwọn ìletò wọn ní láti wá ní àkókò dé àkókò láti pín iṣẹ́ ìsìn wọn fún àkókò ọjọ́ méje.
26
Ṣùgbọ́n àwọn olórí alábojútó ẹnu-ọ̀nà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n jẹ́ ará Lefi ni a yàn fún àwọn iyàrá àti àwọn àpótí ìṣúra ní ilé Ọlọ́run.
27
Wọ́n á lo gbogbo òru ní dídúró yí ilé Ọlọ́run ká, nítorí wọ́n ní láti ṣọ́ ọ, wọ́n sì ní àṣẹ sí kọ́kọ́rọ́ fún ṣíṣí i ní àràárọ̀.
28
Díẹ̀ wà ní ìdí ohun èlò tí à ń lò fún ìsìn ilé Ọlọ́run; wọn a máa kà á nígbà tí wọ́n gbé e wọlé àti nígbà tí a kó wọn jáde.
29
Àwọn mìíràn ni a yàn láti bojútó ohun èlò àti gbogbo ohun èlò ilé tí a yà sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run, àti ìyẹ̀fun àti ọtí èso àjàrà àti òróró náà, tùràrí àti tùràrí olóòórùn dídùn.
30
Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn àlùfáà ni ó ń bojútó pípò tùràrí olóòórùn dídùn papọ̀.
31
Ará Lefi tí a sọ ní Mattitiah àkọ́bí ọmọkùnrin Ṣallumu ará Kora ni a yàn, tí ń ṣe alábojútó ohun tí a dín.
32
Àti nínú àwọn arákùnrin wọn, nínú àwọn ọmọ Kohati tó ń ṣe ìtọ́jú àkàrà ìfihàn, láti máa pèsè rẹ̀ ní ọjọọjọ́ ìsinmi.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options