1 Kronika 7:13
Ń ṣàfihàn ẹsẹ 13 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
10
Ọmọ Jediaeli: Bilhani. Àwọn ọmọ Bilhani: Jeuṣi Benjamini, Ehudu, Kenaana, Setamu, Tarṣiṣi àti Ahiṣahari.
11
Gbogbo àwọn ọmọ Jediaeli jẹ́ olórí. Àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún ó lé nígba (17,200) akọni ọkùnrin ni ó ti ṣetán láti jáde lọ sí ogun.
12
Àti Ṣuppimu, àti Huppimu, àwọn ọmọ Iri, àti Huṣimu, àwọn ọmọ Aheri.
13
Àwọn ọmọ Naftali: Jasieli, Guni, Jeseri àti Ṣallumu—ọmọ rẹ̀ nípa Biliha.
14
Àwọn ìran ọmọ Manase: Asrieli jẹ́ ìran ọmọ rẹ̀ ní ipasẹ̀ àlè rẹ̀ ará Aramu ó bí Makiri baba Gileadi.
15
Makiri sì mú ìyàwó láti àárín àwọn ará Huppimu àti Ṣuppimu. Orúkọ arábìnrin rẹ̀ a máa jẹ́ Maaka. Orúkọ ìran ọmọ mìíràn a máa jẹ́ Selofehadi, tí ó ní àwọn ọmọbìnrin nìkan ṣoṣo.
16
Maaka, ìyàwó Makiri bí ọmọkùnrin kan. Ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Peresi. Ó sì pe arákùnrin rẹ̀ ní Ṣereṣi, àwọn ọmọ rẹ̀ sì ní Ulamu àti Rakemu.
Settings