1 Kronika 6:71-76
71
Àwọn ará Gerṣoni gbà nǹkan wọ̀nyí. Láti ààbọ̀ ẹ̀yà ti Manase wọ́n gba Golani ní Baṣani àti pẹ̀lú Aṣtarotu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù wọn.
72
Láti ẹ̀yà Isakari wọ́n gba Kedeṣi, Daberati
73
Ramoti àti Anenu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
74
Láti ẹ̀yà Aṣeri wọ́n gba Maṣali, Abdoni,
75
Hukoki àti Rehobu lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
76
Pẹ̀lú láti ẹ̀yà Naftali wọ́n gba Kedeṣi ní Galili, Hammoni àti Kiriataimu, lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko tútù ilẹ̀ wọn.
Settings