1 Kronika 6:31-38
31
Èyí ní àwọn ọkùnrin Dafidi tí a fi sí ìdí orin nínú ilé Olúwa lẹ́yìn tí àpótí ẹ̀rí ti wá láti sinmi níbẹ̀.
32
Wọ́n jíṣẹ́ pẹ̀lú orin níwájú àgọ́ ìpàdé títí tí Solomoni fi kọ́ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu. Wọ́n ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà tí a fi lélẹ̀ fún wọn.
33
Wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ó sìn pẹ̀lú ọmọ wọn. Láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Kohati: Hemani olùkọrin, ọmọ Joẹli, ọmọ Samuẹli,
34
ọmọ Elkana, ọmọ Jerohamu, ọmọ Elieli, ọmọ Toha,
35
ọmọ Sufu, ọmọ Elkana, ọmọ Mahati, ọmọ Amasai,
36
ọmọ Elkana, ọmọ Joẹli, ọmọ Asariah, ọmọ Sefaniah,
37
ọmọ Tahati, ọmọ Asiri, ọmọ Ebiasafi, ọmọ Kora,
38
ọmọ Isari, ọmọ Kohati, ọmọ Lefi, ọmọ Israẹli;
Settings