1 Kronika 28:2-7
2
Ọba Dafidi dìde dúró ní ẹsẹ̀ rẹ̀, o sì wí pé, “Fetísílẹ̀ sí mi, ẹ̀yin ará mi àti ẹ̀yin ènìyàn mi. Èmi ní o ni lọ́kàn mi láti kọ́ ilé gẹ́gẹ́ bí ibi ìsinmi fún àpótí ẹ̀rí tí Olúwa fún àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọ́run wa, èmi sì gbèrò láti kọ́ ọ.
3
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún mi pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ ilé fún orúkọ mi, nítorí ìwọ jẹ́ jagunjagun, ìwọ sì ti tàjẹ̀ sílẹ̀.’
4
“Síbẹ̀ Olúwa, Ọlọ́run Israẹli yàn mí láti gbogbo ìdílé láti jẹ́ ọba lórí Israẹli, títí láé. Ó yan Juda gẹ́gẹ́ bí olórí, àti láti ilé Juda, ó yan ìdílé mi, àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ baba à mí, ó tẹ́ Ẹ lọ́rùn láti fi mí ṣe ọba lórí gbogbo Israẹli.
5
Nínú gbogbo àwọn ọmọ mi pẹ̀lú Olúwa ti fún mi ní púpọ̀, ó ti yan ọmọ mi Solomoni láti jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba ti Olúwa lórí Israẹli.
6
Ó wí fún mi pé, Solomoni ọmọ rẹ ni ẹni tí yóò kọ́ ilé mi àti àwọn ààfin mi, nítorí tí èmi ti yàn án láti ṣe ọmọ mi èmi yóò sì jẹ́ baba a rẹ̀.
7
Èmi yóò fi ìdí ìjọba rẹ̀ kalẹ̀ títí láé tí kò bá kọ̀ láti gbé àṣẹ àti òfin mi jáde, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe é ní àsìkò yìí.
Settings