Skip to content
1 Kronika 26:20

1 Kronika 26:20

Ń ṣàfihàn ẹsẹ 20 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
17
Àwọn ará Lefi mẹ́fà ní ó wà ní ọjọ́ kan ní ìhà ìlà-oòrùn, mẹ́rin ní ọjọ́ kan ní ìhà àríwá, mẹ́rin ní ọjọ́ kan ní ìhà gúúsù àti méjì ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ní ilé ìṣúra.
18
Ní ti ilé ẹjọ́ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn, mẹ́rin sì wà ní ojú ọ̀nà àti méjì ní ilé ẹjọ́ fúnra rẹ̀.
19
Wọ̀nyí ni ìpín ti àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà tí wọ́n jẹ́ àwọn ìran ọmọ Kora àti Merari.
20
Láti inú àwọn ọmọ Lefi, Ahijah ni ó wà lórí ìṣúra ti ilé Ọlọ́run àti lórí ìṣúra nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a yà sí mímọ́.
21
Àwọn ìran ọmọ Laadani tí wọn jẹ́ ará Gerṣoni nípasẹ̀ Laadani àti tí wọn jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé tí ó jẹ́ ti Laadani ará Gerṣoni ni Jehieli.
22
Àwọn ọmọ Jehieli, Setamu àti arákùnrin rẹ̀ Joẹli. Wọ́n ṣalábojútó ilé ìṣúra ti ilé ìṣúra ti ilé Olúwa.
23
Láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Amramu, àwọn ará Isari, àwọn ará Hebroni àti àwọn ará Usieli.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 90 chars

Options