Skip to content
1 Kronika 24:1-18

1 Kronika 24:1-18

1
Àwọn wọ̀nyí sì ni pínpín àwọn ọmọ Aaroni. Àwọn ọmọ Aaroni ni Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari.
2
Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú kí ó tó di wí pé baba wọn kú, wọn kò sì ní àwọn ọmọ; bẹ́ẹ̀ ni Eleasari àti Itamari sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.
3
Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Sadoku ọmọ Eleasari àti Ahimeleki ọmọ Itamari, Dafidi sì yà wọ́n nípa nínú ìpín fún ìyàsọ́tọ̀ àwọn iṣẹ́ ìsìn wọn.
4
A rí ọ̀pọ̀ àwọn olórí lára àwọn ọmọ Eleasari ju lára àwọn ọmọ Itamari lọ, wọ́n sì pín wọn lẹ́sẹ lẹ́sẹ: mẹ́rìndínlógún olórí láti ìdílé ọmọ Eleasari ìran wọn àti olórí méjọ ìdílé láti ara àwọn ọmọ Itamari.
5
Wọ́n sì pín wọn láìṣègbè nípa yíya ìpín, nítorí àwọn olórí ibi mímọ́ àti àwọn olórí ilé Ọlọ́run wà láàrín àwọn ọmọ méjèèjì Eleasari àti Itamari.
6
Ṣemaiah ọmọ Netaneli, akọ̀wé ọ̀kan lára àwọn ọmọ Lefi sì kọ orúkọ wọn níwájú ọba àti àwọn ìjòyè: Sadoku àlùfáà, Ahimeleki ọmọ Abiatari àti olórí ìdílé àwọn àlùfáà tí a mú láti ọ̀dọ̀ Eleasari àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ Itamari.
7
Ìpín èkínní jáde sí Jehoiaribu, èkejì sí Jedaiah,
8
ẹlẹ́ẹ̀kẹta sì ni Harimu, ẹ̀kẹrin sì ní Seorimu,
9
ẹ̀karùnún sì ni Malkiah, ẹlẹ́ẹ̀kẹfà sì ni Mijamini,
10
èkeje sì ni Hakosi, ẹlẹ́ẹ̀kẹjọ sí ni Abijah,
11
ẹ̀kẹsànán sì ni Jeṣua, ẹ̀kẹwàá sì ni Ṣekaniah,
12
ẹ̀kọkànlá sì ni Eliaṣibu, ẹlẹ́ẹ̀kẹjìlá sì ni Jakimu,
13
ẹ̀kẹtàlá sì ni Hupa, ẹlẹ́ẹ̀kẹrìnlá sì ni Jeṣebeabu,
14
ẹ̀kẹdógún sì ni Bilgah, ẹ̀kẹrìndínlógún sì ni Immeri,
15
ẹ̀kẹtàdínlógún sì ni Hesiri, èkejìdínlógún sì ni Hafisesi,
16
ẹ̀kọkàndínlógún sì ni Petahiah, ogún sì ni Jeheskeli,
17
ẹ̀kọkànlélógún sì ni Jakini, ẹ̀kẹrìnlélógún sì ni Gamuli,
18
ẹ̀kẹtàlélógún sì ni Delaiah, ẹ̀kẹrìnlélógún sì ni Maasiah.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options