Benhadad
A tún mọ̀ ọ́n sí: Ben-hadad
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Benhadad
Bẹ́ẹ̀ ni ìbínú Olúwa ru sí àwọn ọmọ Israẹli, àti fún ìgbà pípẹ́, ó fi wọ́n pamọ́ sí abẹ́ agbára ọba Hasaeli ọba Siria àti Beni-Hadadi ọmọ rẹ̀.
Hasaeli ọba Siria kú, Beni-Hadadi ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
Nígbà náà, Jehoaṣi ọmọ Jehoahasi gbà padà kúrò lọ́wọ́ Beni-Hadadi ọmọ Hasaeli àwọn ìlú tí ó ti gbà nínú ogun látọ̀dọ̀ baba rẹ̀ Jehoahasi. Ní ẹ̀ẹ̀mẹta, Jehoaṣi ṣẹ́gun rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó gba ìlú àwọn ọmọ Israẹli padà.
Èmi yóò rán iná sí ilé Hasaeli, èyí ti yóò jó àwọn ààfin Beni-Hadadi run.