Skip to content
Sekariah 3:1-7

Sekariah 3:1-7

1
Ó sì fi Joṣua olórí àlùfáà hàn mí, ó dúró níwájú angẹli Olúwa, Satani sí dúró lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ láti kọjú ìjà sí i.
2
Olúwa si wí fún Satani pé, “Olúwa bá ọ wí ìwọ Satani; àní Olúwa tí ó ti yan Jerusalẹmu, bá ọ wí, igi iná kọ́ ni èyí tí a mú kúrò nínú iná?”
3
A sì wọ Joṣua ni aṣọ èérí, ó sì dúró níwájú angẹli náà.
4
Ó sì dáhùn ó wí fún àwọn tí ó dúró níwájú rẹ̀ pé, “Bọ́ aṣọ èérí nì kúrò ní ara rẹ̀.” Ó sì wí fún Joṣua pé, “Wò ó, mo mú kí àìṣedéédéé rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, èmi yóò sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ ẹ̀yẹ.”
5
Mó sì wí pé, “Jẹ kí wọn fi gèlè mímọ́ wé e lórí.” Wọn sì fi gèlè mímọ́ wé e lórí, wọn sì fi aṣọ wọ̀ ọ́. Angẹli Olúwa sì dúró tì í.
6
Angẹli Olúwa sì tẹnumọ́ ọn fún Joṣua pé:
7
“Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Bí ìwọ ọ́ bá rìn ní ọ̀nà mi, bí ìwọ yóò bá sì pa àṣẹ mi mọ́, ìwọ yóò sì ṣe ìdájọ́ ilé mi pẹ̀lú, ìwọ yóò sì ṣe àkóso ààfin mi, èmi yóò fún ọ ní ààyè láti rìn láàrín àwọn tí ó dúró yìí.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options