Orin Solomoni 4:12-16
12
Arábìnrin mi ni ọgbà tí a sọ, arábìnrin mi, ìyàwó mi; ìsun tí a sé mọ́, orísun tí a fi èdìdì dì.
13
Ohun ọ̀gbìn rẹ àgbàlá pomegiranate ni ti òun ti àṣàyàn èso; kipiresi àti nadi,
14
nadi àti Safironi, kalamusi àti kinamoni, àti gbogbo igi olóòórùn dídùn, òjìá àti aloe pẹ̀lú irú wọn.
15
Ìwọ ni ọgbà orísun, kànga omi ìyè, ìṣàn omi láti Lebanoni wá.
16
Jí ìwọ afẹ́fẹ́ àríwá kí o sì wá, afẹ́fẹ́ gúúsù! Fẹ́ lórí ọgbà mi, kí àwọn òórùn dídùn inú rẹ lè rùn jáde. Jẹ́ kí olùfẹ́ mi wá sínú ọgbà a rẹ̀ kí ó sì jẹ àṣàyàn èso rẹ̀.
Settings