Saamu 99:1-4
1
Olúwa jẹ ọba; jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì Ó jókòó lórí ìtẹ́ kérúbù jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì.
2
Olúwa tóbi ní Sioni; Ó sì ga jù gbogbo orílẹ̀-èdè lọ.
3
Kí wọ́n sì yin orúkọ rẹ̀ tí ó tóbi tí ó ni ẹ̀rù, Mímọ́ ni Òun.
4
Ọba náà ní agbára, ó sì fẹ́ òdodo, ìwọ fi ìdí àìṣègbè múlẹ̀; ìwọ ṣe ohun tí ó tọ́ àti ohun tí ó yẹ nínú Jakọbu.
Settings