Saamu 89:1-4
1
Maskili ti Etani ará Esra. Èmi kọrin títóbi ìfẹ́ Olúwa títí láé; pẹ̀lú ẹnu mi ní èmi yóò jẹ́ kí a mọ òtítọ́ rẹ láti ìran dé ìran.
2
Èmi ó wí pé, ìfẹ́ rẹ dúró títí láé, pé ìwọ gbe òtítọ́ rẹ kalẹ̀ ní ọ̀run fúnra rẹ̀.
3
Ìwọ wí pé, “Èmi ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn àyànfẹ́ mi mo ti búra fún Dafidi ìránṣẹ́ mi.
4
‘Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ múlẹ̀ títí láé èmí ó sì máa gbe ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’ ”
Settings