Saamu 74:4-11
4
Àwọn ọ̀tá rẹ ń bú ramúramù láàrín ènìyàn rẹ, wọ́n ń gbé àsíá wọn sókè fún àmì.
5
Wọ́n ń rí bí ọkùnrin tí ó gbé àáké rẹ̀ sókè láti gé igi igbó dídí.
6
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, iṣẹ́ ọnà fínfín, ni wọ́n fi àáké wó lulẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan náà.
7
Wọ́n sun ibi mímọ́ rẹ lulẹ̀ wọ́n ba ibùgbé orúkọ rẹ jẹ́.
8
Wọ́n wí ní ọkàn wọn. “Àwa ó run wọ́n pátápátá!” Wọ́n sun gbogbo ibi ìjọ́sìn Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà.
9
A kò fún wa ní àmì iṣẹ́ ìyanu kankan; kò sí wòlíì kankan ẹnìkankan wa kò mọ ìgbà tí eléyìí yóò dà.
10
Àwọn ọ̀tá yóò ti kùn sí ọ pẹ́ tó, Ọlọ́run? Àwọn ọ̀tá yóò ha ba orúkọ rẹ jẹ́ títí láé?
11
Èéṣe tí ìwọ fi dá ọwọ́ rẹ dúró, ọwọ́ ọ̀tún rẹ? Mú un kúrò nínú ìṣẹ́po aṣọ rẹ kí o sì run wọ́n!
Settings