Skip to content
Saamu 68:7-18

Saamu 68:7-18

7
Nígbà tí ìwọ bá jáde lónìí níwájú àwọn ènìyàn rẹ, Ọlọ́run, tí ń kọjá lọ láàrín aginjù, Sela.
8
Ilẹ̀ mì títí, àwọn ọ̀run ń rọ òjò jáde, níwájú Ọlọ́run, ẹni Sinai, níwájú Ọlọ́run, Ọlọ́run Israẹli.
9
Ìwọ fún wa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ òjò, Ọlọ́run; ìwọ tu ilẹ̀ ìní rẹ̀ lára nígbà tí ó rẹ̀ ẹ́ tan.
10
Àwọn ènìyàn rẹ tẹ̀dó síbẹ̀ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní rẹ, Ọlọ́run, ìwọ pèsè fún àwọn aláìní.
11
Olúwa ti pàṣẹ ọ̀rọ̀, púpọ̀ ní ogun àwọn ẹni tí ó ń ròyìn rẹ̀.
12
“Àwọn ọba àti àwọn ológun yára sálọ; obìnrin tí ó sì jókòó ni ilé ní ń pín ìkógun náà.
13
Nígbà tí ẹ̀yin dùbúlẹ̀ láàrín agbo ẹran, nígbà náà ni ẹ̀yin ó dàbí ìyẹ́ àdàbà ti a bò ní fàdákà, àti ìyẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú wúrà pupa.”
14
Nígbà tí Olódùmarè fọ́n àwọn ọba ká ní ilẹ̀ náà, ó dàbí òjò dídi ní Salmoni.
15
Òkè Baṣani jẹ́ òkè Ọlọ́run; òkè tí ó ní orí púpọ̀ ni òkè Baṣani.
16
Kí ló dé tí ẹ̀yin fi ń ṣe ìlara, ẹ̀yin òkè wúwo, òkè tí Ọlọ́run ti fẹ́ láti jẹ ọba níbi tí Olúwa fúnra rẹ̀ yóò máa gbé títí láé?
17
Ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ni kẹ̀kẹ́ ogun Ọlọ́run ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rún; Olúwa ń bẹ láàrín wọn, ní Sinai ni ibi mímọ́ rẹ̀.
18
Ìwọ ti gòkè sí ibi gíga ìwọ ti di ìgbèkùn ní ìgbèkùn lọ; ìwọ ti gba ẹ̀bùn fún ènìyàn: nítòótọ́, fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ pẹ̀lú, kí Olúwa Ọlọ́run lè máa bá wọn gbé.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options