Saamu 48:1-7
1
Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora. Ẹni ńlá ní Olúwa, tí ó sì yẹ láti máa yìn ní ìlú Ọlọ́run wa, lórí òkè mímọ́ rẹ̀.
2
Ó dára nínú ipò ìtẹ́ rẹ̀, ayọ̀ gbogbo ayé, òkè Sioni, ní ìhà àríwá ní ìlú ọba ńlá.
3
Ọlọ́run wà nínú ààbò ààfin rẹ̀; ó fi ara rẹ̀ hàn láti jẹ́ odi alágbára.
4
Nígbà tí àwọn ọba kógun jọ pọ̀, wọ́n jùmọ̀ ń kọjá lọ.
5
Wọn rí i, bẹ́ẹ̀ ni ẹnu sì yà wọ́n, a yọ wọ́n lẹ́nu, wọ́n yára lọ.
6
Ẹ̀rù sì bà wọ́n níbẹ̀, ìrora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó wà nínú ìrọbí.
7
Ìwọ bà wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ orí omi Tarṣiṣi, wọ́n fọ́nká láti ọwọ́ ìjì ìlà-oòrùn.
Settings