1
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu. Ẹ pàtẹ́wọ́, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ẹ hó sí Ọlọ́run pẹ̀lú orin ayọ̀ tó rinlẹ̀.
2
Báwo ni Olúwa Ọ̀gá-ògo ti ní ẹ̀rù tó ọba ńlá lórí gbogbo ayé.
3
Ṣe ìkápá àwọn orílẹ̀-èdè lábẹ́ wa àwọn ènìyàn lábẹ́ ẹsẹ̀ wa
4
Ó mú ilẹ̀ ìní wa fún wa, ọlá Jakọbu, ẹni tí ó fẹ́ wa.