Saamu 22:22-31
22
Èmi yóò kéde orúkọ rẹ láàrín arákùnrin àti arábìnrin mi; nínú ìjọ ni èmi yóò máa yìn ọ́.
23
Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ yìn ín! Gbogbo ẹ̀yin ìran Jakọbu, ẹ fi ògo fún un! Ẹ dìde fún un tẹ̀rù tẹ̀rù, ẹ̀yin irú-ọmọ Israẹli!
24
Nítorí pé òun kò ṣátá, bẹ́ẹ̀ ni kò sì kórìíra ìpọ́njú àwọn tí a ni lára; kò sì fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún mi ṣùgbọ́n ó gbọ́ nígbà tí mo ké pè é.
25
Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìyìn mi yóò ti wá nínú àjọ ńlá; ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò san níwájú àwọn tí o bẹ̀rù rẹ̀
26
tálákà yóò jẹ yóò sì yó; àwọn tí n wá Olúwa yóò yin jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ wà láààyè títí ayérayé!
27
Gbogbo òpin ayé ni yóò rántí wọn yóò sì yípadà sí Olúwa, àti gbogbo ìdílé orílẹ̀-èdè ni wọn yóò jọ́sìn níwájú rẹ̀,
28
nítorí ìjọba ni ti Olúwa. Òun ni ó ń pàṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè.
29
Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn olówó ayé wọn yóò ṣe àsè, wọn yóò sì sìn; gbogbo àwọn tí ó wọ inú ilẹ̀ lọ yóò kúnlẹ̀ ní iwájú rẹ̀ àti ẹni tí kò lè pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́ ni ààyè.
30
Irú-ọmọ rẹ̀ yóò sìn ín; a ó sọ fún àwọn ìran tí ń bọ̀ nípa Olúwa.
31
Wọn yóò polongo òdodo rẹ̀ sí àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí, wí pé, òun ni ó ṣe èyí.
Settings