Skip to content
Saamu 18:29-45

Saamu 18:29-45

29
Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, èmi sáré tọ ogun lọ; pẹ̀lú Ọlọ́run mi mo lè fo odi kan.
30
Bí ó ṣe ti Ọlọ́run mi, ọ̀nà rẹ̀ pé, a ti rídìí ọ̀rọ̀ Olúwa òun ni àpáta ààbò fún gbogbo àwọn tí ó fi ṣe ààbò.
31
Nítorí ta ni ṣe Ọlọ́run bí kò ṣe Olúwa? Ta ní àpáta bí kò ṣe Olúwa wa?
32
Ọlọ́run ni ẹni tí ó fi agbára dì mí ní àmùrè ó sì mú ọ̀nà mi pé.
33
Ó ṣe ẹsẹ̀ mi gẹ́gẹ́ bi ẹsẹ̀ abo àgbọ̀nrín; ó jẹ́ ki n lè dúró lórí ibi gíga.
34
Ó kọ́ ọwọ́ mi ni ogun jíjà; apá mi lè tẹ ọrùn idẹ.
35
Ìwọ fi asà ìṣẹ́gun rẹ̀ fún mi, ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbé mí dúró; àti ìwà pẹ̀lẹ́ rẹ̀ sọ mí di ńlá.
36
Ìwọ sọ ìrìn ẹsẹ̀ mi di ńlá ní ìsàlẹ̀ mi, kí kókó-ẹsẹ̀ mi má ṣe yẹ̀.
37
Èmi lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi sì bá wọn èmi kò sì padà lẹ́yìn wọn títí a fi run wọ́n.
38
Èmi sá wọn ní ọgbẹ́ tí wọn ko fi le è dìde; wọ́n ṣubú ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi.
39
Nítorí ìwọ fi agbára dì mí ní àmùrè fún ogun náà; ìwọ ti mú àwọn tí ó dìde si mí tẹríba ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi.
40
Ìwọ yí ẹ̀yìn àwọn ọ̀tá mí padà sí mi èmi sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run.
41
Wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbà wọ́n, àní sí Olúwa, ṣùgbọ́n kò dá wọn lóhùn.
42
Mo lù wọ́n gẹ́gẹ́ bí eruku níwájú afẹ́fẹ́; mo dà wọ́n síta gẹ́gẹ́ bí ẹrọ̀fọ̀.
43
Ìwọ ti gbà mí lọ́wọ́ ìkọlù àwọn ènìyàn; Ìwọ ti fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn ènìyàn ti èmi kò mọ, yóò sì máa sìn mí,
44
ni wéré ti wọ́n gbọ́ ohùn mi, wọ́n pa àṣẹ mi mọ́; àwọn ọmọ àjèjì yóò tẹríba fún mi.
45
Àyà yóò pá àlejò; wọn yóò sì fi ìbẹ̀rù jáde láti ibi kọ́lọ́fín wọn.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options