Saamu 18:20-30
20
Olúwa ti hùwà sí mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi; gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi, ó ti fi èrè fún mi.
21
Nítorí mo ti pa ọ̀nà Olúwa mọ́; èmi kò ṣe búburú nípa yíyí padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi.
22
Gbogbo òfin rẹ̀ ni ó wà níwájú mi; èmi kò sì yípadà kúrò nínú ìlànà rẹ̀.
23
Mo ti jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú rẹ̀; mo sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.
24
Olúwa san ẹ̀san fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi; gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi níwájú rẹ̀.
25
Fún olóòtítọ́ ni ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní olóòtítọ́, sí aláìlẹ́bi, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní aláìlẹ́bi,
26
sí ọlọ́kàn mímọ́, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní ọlọ́kàn mímọ́, ṣùgbọ́n sí ọlọ́kàn-wíwọ́, ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ní òǹrorò.
27
O pa onírẹ̀lẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n ó rẹ àwọn ti ń gbéraga sílẹ̀.
28
Ìwọ, Olúwa, jẹ́ kí fìtílà mi kí ó máa tàn; Ọlọ́run mi, yí òkùnkùn mi padà sí ìmọ́lẹ̀.
29
Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, èmi sáré tọ ogun lọ; pẹ̀lú Ọlọ́run mi mo lè fo odi kan.
30
Bí ó ṣe ti Ọlọ́run mi, ọ̀nà rẹ̀ pé, a ti rídìí ọ̀rọ̀ Olúwa òun ni àpáta ààbò fún gbogbo àwọn tí ó fi ṣe ààbò.
Settings