Skip to content
Saamu 16:5-8

Ọlọ́run ni ìpín mi tí ó dájú

Saamu 16:5-8

Ọlọ́run ni ìpín mi tí ó dájú

5
Olúwa, ni ìpín ìní mi tí mo yàn àti ago mi, ó ti pa ohun tí í ṣe tèmi mọ́.
6
Okùn ààlà ilẹ̀ ti bọ́ sí ọ̀dọ̀ mi ní ibi dídára; nítòótọ́ mo ti ní ogún rere.
7
Èmi yóò yin Olúwa, ẹni tí ó gbà mí ní ìyànjú; ní òru, ọkàn mí ń bá mi sọ̀rọ̀.
8
Mo ti gbé Olúwa síwájú mi ní ìgbà gbogbo. Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mì mí.

See also

Where else Scripture says this.

  • Ìṣe àwọn Aposteli 2:25

    Dafidi tí wí nípa tirẹ̀ pé: “ ‘Mo rí Olúwa nígbà gbogbo níwájú mí, nítorí tí ó ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún mi, a kì ó ṣí mi ní ipò.
    from verse 8
  • Ìṣe àwọn Aposteli 2:28

    Ìwọ mú mi mọ ọ̀nà ìyè, ìwọ yóò mú mi kún fún ayọ̀ ni iwájú rẹ.’
    from verse 8
  • Saamu 62:6

    Òun nìkan ní àpáta àti ìgbàlà mi; Òun ni ààbò mi, a kì yóò ṣí mi ní ipò.
    from verse 8
  • Saamu 121:5

    Olúwa ni olùpamọ́ rẹ; Olúwa ní òjìji rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.
    from verse 8
  • Saamu 73:23

    Síbẹ̀ mo wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo; ìwọ di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.
    from verse 8
  • Saamu 73:26

    Ara mi àti ọkàn mi le è kùnà ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni agbára ẹ̀mí mi àti ìpín mi títí láé.
    from verse 5
  • Saamu 110:5

    Olúwa, ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni yóò lu àwọn ọba bolẹ̀ ni ọjọ́ ìbínú rẹ̀.
    from verse 8
  • Saamu 109:31

    Nítorí ó dúró ní apá ọ̀tún aláìní láti gbà á lọ́wọ́ àwọn tí ń dá ọkàn rẹ̀ lẹ́bi.
    from verse 8
  • Saamu 142:5

    Èmi kígbe sí ọ, Olúwa: èmi wí pé, “Ìwọ ni ààbò mi, ìpín mi ní ilẹ̀ alààyè.”
    from verse 5
  • Ẹkún Jeremiah 3:24

    Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni Olúwa; nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́.
    from verse 5
  • Saamu 23:5

    Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú mi ní ojú àwọn ọ̀tá à mi. Ìwọ ta òróró sí mi ní orí; ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀.
    from verse 5
  • Jeremiah 3:19

    “Èmi fúnra mi sọ wí pé, “ ‘Báwo ni inú mi yóò ti dùn tó, kí èmi kí ó tọ́ ọ bí ọmọkùnrin kí n sì fún ọ ní ilẹ̀ tí ó tó.’ Mo rò pé ìwọ yóò pè mí ní ‘Baba mi’ o kò sì ní ṣàì tọ̀ mí lẹ́yìn.
    from verse 6
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options