Saamu16
Listen to this chapter
0:00
0:00
1
Miktamu ti Dafidi. Pa mí mọ́, Ọlọ́run, nítorí nínú rẹ ni ààbò mi wà.
2
Mo sọ fún Olúwa, “Ìwọ ni Olúwa mi, lẹ́yìn rẹ èmi kò ní ìre kan.”
3
Sí àwọn ènìyàn tí ó wà ní ayé, àwọn ni ológo nínú èyí tí ayọ̀ mí wà.
4
Ìṣòro àwọn wọ̀n-ọn-nì yóò pọ̀ sí i, àní àwọn tí ń tọ ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn. Ẹbọ ohun mímu ẹ̀jẹ̀ wọn ni èmi kì yóò ta sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá orúkọ wọn lẹ́nu mi.
5
Olúwa, ni ìpín ìní mi tí mo yàn àti ago mi, ó ti pa ohun tí í ṣe tèmi mọ́.
6
Okùn ààlà ilẹ̀ ti bọ́ sí ọ̀dọ̀ mi ní ibi dídára; nítòótọ́ mo ti ní ogún rere.
7
Èmi yóò yin Olúwa, ẹni tí ó gbà mí ní ìyànjú; ní òru, ọkàn mí ń bá mi sọ̀rọ̀.
8
Mo ti gbé Olúwa síwájú mi ní ìgbà gbogbo. Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mì mí.
9
Nítorí èyí, ọkàn mi yọ̀, ahọ́n mi pẹ̀lú ń fò fáyọ̀; ara mi pẹ̀lú yóò sinmi ní ààbò,
10
nítorí ìwọ kò ní fi ọ̀kan sílẹ̀ nínú isà òkú, tàbí kí ìwọ jẹ́ kí ẹni mímọ́ rẹ kí ó rí ìdíbàjẹ́.
11
Ìwọ ti fi ipa ọ̀nà ìyè hàn mí; Ìwọ yóò kún mi pẹ̀lú ayọ̀ ní iwájú rẹ, pẹ̀lú ìdùnnú ayérayé ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.
Use ← → arrow keys to navigate
Settings
Reading Style
Typeface
Font Size px
Options
Study Note