Saamu 124:1-5
1
Orin fún ìgòkè. Ti Dafidi. “Ìbá má ṣe pé Olúwa tí ó ti wà fún wa,” kí ni Israẹli kí ó máa wí nísinsin yìí;
2
ìbá má ṣe pé Olúwa tó wà ní tiwa, nígbà tí àwọn ènìyàn gbógun sí wa,
3
nígbà náà ni wọn ò bá gbé wà mì láààyè nígbà tí ìbínú wọn ru sí wa,
4
nígbà náà ni omi wọ̀n-ọn-nì ìbá bò wá mọ́lẹ̀,
5
nígbà náà ni agbéraga omi ìbá borí ọkàn wa.
Settings