Skip to content
Saamu 116:12-19

Saamu 116:12-19

12
Kí ni èmi yóò san fún Olúwa nítorí gbogbo rere rẹ̀ sí mi?
13
Èmi yóò gbé ago ìgbàlà sókè èmi yóò sì máa ké pe orúkọ Olúwa.
14
Èmi yóò mú ìlérí mi ṣẹ sí Olúwa ní ojú àwọn ènìyàn rẹ̀.
15
Iyebíye ní ojú Olúwa àti ikú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.
16
Olúwa, nítòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ ni mo jẹ́; èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ; ó ti tú mi sílẹ̀ nínú ìdè mi.
17
Èmi yóò rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ èmi yóò sì ké pe orúkọ Olúwa.
18
Èmi yóò mú ìlérí mi sẹ sí Olúwa ní ojú gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀,
19
nínú àgbàlá ilé Olúwa ní àárín rẹ̀, ìwọ Jerusalẹmu. Ẹ yin Olúwa.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options