Skip to content
Saamu 104:1-9

Saamu 104:1-9

1
Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi. Olúwa Ọlọ́run mi, ìwọ tóbi jọjọ; ọlá àti ọláńlá ni ìwọ wọ̀ ní aṣọ.
2
Ìwọ fi ìmọ́lẹ̀ bo ara rẹ gẹ́gẹ́ bí aṣọ; ó tẹ ọ̀run bí títẹ́ ẹní,
3
ìwọ tí ó fi omi ṣe ìtì igi àjà ìyẹ̀wù rẹ. Ìwọ tí o ṣe àwọsánmọ̀ ní kẹ̀kẹ́ ogun rẹ ìwọ tí ó ń rìn lórí apá ìyẹ́ afẹ́fẹ́.
4
Ó fi ẹ̀fúùfù ṣe àwọn ìránṣẹ́ rẹ, ọ̀wọ́-iná ni àwọn olùránṣẹ́ rẹ.
5
O fi ayé gúnlẹ̀ lórí àwọn ìpìlẹ̀; tí a kò le è mì láéláé.
6
Ìwọ fi ibú omi bò ó mọ́lẹ̀ bí aṣọ; àwọn omi sì dúró lórí àwọn òkè ńlá.
7
Ṣùgbọ́n nípa ìbáwí rẹ ni àwọn omi lọ, nípa ohùn àrá rẹ ni wọ́n sálọ.
8
wọ́n sàn kọjá lórí àwọn òkè, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀, sí ibi tí ìwọ ti yàn fún wọn.
9
Ìwọ gbé òpin tí wọn kò lè kọjá rẹ̀ kálẹ̀; láéláé ni wọ́n kò ní lè bo ayé mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options