Àwọn ọ̀rọ̀ iye: àwọn ẹ̀dá kéékèèké ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n
24
“Àwọn ohun mẹ́rin ló kéré láyé síbẹ̀ wọ́n gbọ́n gidigidi.
25
Àwọn èèrà jẹ́ aláìlágbára ẹ̀dá, síbẹ̀ wọ́n kó oúnjẹ wọn pamọ́ ní àsìkò òjò.
26
Ehoro jẹ́ aláìlágbára ẹ̀dá; síbẹ̀ wọ́n ń ṣe ihò wọn sí ibi pálapàla àpáta;
27
àwọn eṣú kò ní ọba, síbẹ̀ gbogbo wọ́n ń jáde lọ ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́
28
Ọmọnílé fi ọwọ́ rẹ̀ dì mú, síbẹ̀ a ń rí i ní ààfin ọba.
Settings