Òwe 16:25-33
25
Ọ̀nà kan tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn a ṣokùnfà ikú.
26
Ọkàn alágbàṣe ń ṣiṣẹ́ fún ara rẹ̀; nítorí ebi rẹ̀ mú kí ó máa ṣiṣẹ́ lọ.
27
Ènìyàn búburú ń pète ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì dàbí i iná tí ń jóni.
28
Aláyídáyidà ènìyàn dá ìjà sílẹ̀ olófòófó a sì máa pín ọ̀rẹ́ kòríkòsùn ní yà.
29
Oníjàgídíjàgan ènìyàn tan aládùúgbò rẹ̀ ó sì mú un sọ̀kalẹ̀ lọ sí ọ̀nà tí kò dára.
30
Ẹni tí ń ṣẹ́jú ń pètekéte; ẹni tí ó ṣu ẹnu jọ ń pète aburú.
31
Adé ògo ni ewú orí jẹ́, ìgbé ayé òdodo ní í mú ni dé bẹ̀.
32
Ó sàn láti jẹ́ onísùúrù ju ajagun ènìyàn lọ, ẹni tí ó pa ìbínú mọ́ra ju ajagun ṣẹ́gun ìlú lọ.
33
A ṣẹ́ kèké si ìṣẹ́po aṣọ, ṣùgbọ́n gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa.
Settings