Skip to content
Numeri 3:33-39

Numeri 3:33-39

33
Ti Merari ni ìran Mahili àti Muṣi, àwọn ni ìran Merari.
34
Iye gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ oṣù kan ó lé, èyí tí wọ́n kà jẹ́ igba mọ́kànlélọ́gbọ̀n (6,200).
35
Olórí àwọn ìdílé ìran Merari ni Ṣurieli ọmọ Abihaili. Wọn yóò pa ibùdó wọn sí ìhà àríwá àgọ́.
36
Àwọn ìran Merari ni a yàn fún títọ́jú àwọn férémù àgọ́, ọ̀pá ìdábùú rẹ̀, òpó rẹ̀, ihò òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò tó jẹ mọ́ lílò wọn.
37
Iṣẹ́ wọn tún ni títọ́jú àwọn òpó tó yí àgbàlá ká, ihò òpó rẹ̀, èèkàn àti okùn wọn.
38
Mose àti Aaroni pẹ̀lú àwọn ọmọ yóò pa àgọ́ ní ìdojúkọ ìwọ̀-oòrùn níwájú àgọ́ ìpàdé. Iṣẹ́ wọn ni láti máa mójútó iṣẹ́ ìsìn ibi mímọ́ àti láti máa ṣiṣẹ́ ìsìn fún àwọn ọmọ Israẹli. Àlejò tó bá súnmọ́ ibi mímọ́ yàtọ̀ sí àwọn tí a yàn, pípa ni kí ẹ pa á.
39
Àpapọ̀ iye àwọn ọmọ Lefi tí a kà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose àti Aaroni gẹ́gẹ́ bí ìran wọn, pẹ̀lú gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ oṣù kan ó lé jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000).
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options