Nehemiah 9:12-23
12
Ní ọ̀sán ìwọ darí i wọn pẹ̀lú ọ̀wọn àwọsánmọ̀ àti ní òru ni ìwọ darí i wọn pẹ̀lú ọ̀wọn iná láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀nà tí wọn yóò gbà.
13
“Ìwọ sọ̀kalẹ̀ wá sí orí òkè Sinai; ìwọ bá wọn sọ̀rọ̀ láti ọ̀run. Ìwọ fún wọn ní ìlànà àti àwọn òfin tí ó jẹ́ òdodo tí ó sì tọ́ àti ìlànà tí ó dára.
14
Ìwọ mú ọjọ́ ìsinmi rẹ mímọ́ di mí mọ̀ fún wọn, o sì fún wọn ní àwọn ìlànà, àwọn àṣẹ àti àwọn òfin láti ọwọ́ Mose ìránṣẹ́ rẹ.
15
Ìwọ fún wọn ní oúnjẹ láti ọ̀run wá nígbà tí ebi ń pa wọ́n àti nígbà òǹgbẹ, o fún wọn ní omi láti inú àpáta; o sì sọ fún wọn pé, kí wọ́n lọ láti lọ gba ilẹ̀ náà tí ìwọ ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti fi fún wọn nípa ìgbọ́wọ́sókè.
16
“Ṣùgbọ́n àwọn, baba ńlá wa, wọ́n ṣe ìgbéraga, wọ́n sì ṣe agídí, wọn kò sì tẹríba fún àwọn ìlànà rẹ.
17
Wọ́n kọ̀ láti fetísílẹ̀, wọ́n sì kùnà láti rántí iṣẹ́ ìyanu tí ìwọ ṣe ní àárín wọn. Wọ́n ṣe agídí, nínú ìṣọ̀tẹ̀ wọn, wọ́n yan olórí láti padà sí oko ẹrú wọn. Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run tí ó ń dáríjì, olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú, ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́. Nítorí náà ìwọ kò sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀,
18
nítòótọ́ nígbà tí wọ́n ṣe ẹgbọrọ màlúù dídá, tí wọ́n sì wí pé, ‘Èyí ni Ọlọ́run rẹ tí ó mú ọ gòkè láti Ejibiti wá; tàbí nígbà tí wọ́n sọ ọ̀rọ̀-òdì tí ó burú jàì’.
19
“Nítorí àánú ńlá rẹ, ìwọ kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ní aginjù. Ní ọ̀sán ọ̀wọn ìkùùkuu kò kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn láti ṣe amọ̀nà an wọn, tàbí ọ̀wọ́n iná láti tàn sí wọn ní òru ní ọ̀nà tí wọn yóò rìn.
20
Ìwọ fi ẹ̀mí rere rẹ fún wọn láti kọ́ wọn. Ìwọ kò dá manna rẹ dúró ní ẹnu wọn, ó sì fún wọn ní omi fún òǹgbẹ.
21
Fún ogójì ọdún ni ìwọ fi bọ́ wọn ní aginjù; wọn kò ṣe aláìní ohunkóhun, aṣọ wọn kò gbó bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ wọn kò wú.
22
“Ìwọ fi àwọn ìjọba àti àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ náà fún wọ́n. Wọ́n sì gba ilẹ̀ ọba Sihoni ará a Heṣboni àti ilẹ̀ Ogu ọba Baṣani.
23
Ìwọ ti mú àwọn ọmọ wọn pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ó sì mú wọn wá sí ilẹ̀ tí o ti sọ fún àwọn baba wọn pé kí wọn wọ̀, kí wọn sì jogún un rẹ̀.
Settings