Skip to content
Mika 3:2-12

Mika 3:2-12

2
Ẹ̀yin tí ó kórìíra ìre, tí ẹ sì fẹ́ràn ibi; ẹ̀yin tí ẹ fa awọ ẹran-ara àwọn ènìyàn mi ya kúrò lára wọn àti ẹran-ara wọn kúrò ní egungun wọn;
3
àwọn tí ó jẹ ẹran-ara àwọn ènìyàn mi, wọn sì bọ́ awọ ara wọn kúrò lára wọn. Wọ́n sì fọ́ egungun wọn sí wẹ́wẹ́; wọn sì gé e sí wẹ́wẹ́ bí ẹran inú ìkòkò, bí ẹran inú agbada?”
4
Nígbà náà ni wọn yóò kígbe sí Olúwa, ṣùgbọ́n òun kì yóò dá wọn lóhùn. Ní àkókò náà ni òun yóò fi ojú rẹ̀ pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ wọn, nítorí ibi tí wọ́n ti ṣe.

Ìdálẹ́bi Àwọn Wòlíì Èké

5
Báyìí ni Olúwa wí, “Ní ti àwọn Wòlíì tí ń ṣi àwọn ènìyàn mi lọ́nà, tí ẹnìkan bá fún wọn ní oúnjẹ, wọn yóò kéde àlàáfíà; ṣùgbọ́n tí kò bá fi nǹkan sí wọn ní ẹnu, wọn yóò múra ogun sí i.
6
Nítorí náà òru yóò wá sórí yín, tí ẹ̀yin kì yóò sì rí ìran kankan, òkùnkùn yóò sì kùn fún yín, tí ẹ̀yin kì yóò sì lè sọtẹ́lẹ̀. Oòrùn yóò sì wọ lórí àwọn wòlíì ọjọ́ yóò sì ṣókùnkùn lórí wọn.
7
Ojú yóò sì ti àwọn wòlíì àwọn alásọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú yóò sì gba ìtìjú. Gbogbo wọn ni yóò bo ojú wọn, nítorí kò sí ìdáhùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”
8
Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi kún fún agbára pẹ̀lú ẹ̀mí Olúwa, láti sọ ìré-òfin-kọjá Jakọbu fún un, àti láti sọ ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli fún un.

Ẹ̀sùn Kíkún àti Ìparun Ìkẹyìn

9
Gbọ́ ẹ̀yin olórí ilé Jakọbu, àti ẹ̀yin alákòóso ilé Israẹli, tí ó kórìíra òdodo tí ó sì yí òtítọ́ padà;
10
tí ó kọ́ Sioni pẹ̀lú ìtàjẹ̀ sílẹ̀, àti Jerusalẹmu pẹ̀lú ìwà búburú.
11
Àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe ìdájọ́ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn àlùfáà rẹ̀ sì ń kọ́ni nítorí owó ọ̀yà àwọn wòlíì rẹ̀ pẹ̀lú sì ń sọtẹ́lẹ̀ nítorí owó. Síbẹ̀, wọn gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, wọ́n sì wí pé, “Nítòótọ́, Olúwa wà pẹ̀lú wa! Ibi kan kì yóò bá wa.”
12
Nítorí náà, nítorí tiyín, ni a ó ṣe ro Sioni bí oko, Jerusalẹmu yóò sì di ebè àti òkè tẹmpili bí i ibi gíga igbó.

See also

Where else Scripture says this.

  • Jeremiah 6:13

    “Láti orí ẹni tí ó kéré sí orí ẹni tí ó tóbi ju, gbogbo wọn ni ó sì ní ojúkòkòrò fún èrè, àwọn wòlíì àti àlùfáà lápapọ̀ sì kún fún ẹ̀tàn.
    from verse 11
  • Isaiah 58:1

    “Kígbe rẹ̀ sókè, má ṣe fàsẹ́yìn. Gbé ohùn rẹ sókè bí i ti fèrè. Jẹ́ kí ó di mí mọ̀ fún àwọn ènìyàn mi, ọ̀tẹ̀ wọn, àti fún ilé Jakọbu ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
    from verse 8
  • Isaiah 1:23

    Ọlọ̀tẹ̀ ni àwọn aláṣẹ yín, akẹgbẹ́ àwọn olè, gbogbo wọn ló fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ́n sì ń wá ẹ̀bùn kiri. Wọ́n kì í ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba, ẹjọ́ opó kì í sì í dé iwájú wọn.
    from verse 9
  • 1 Kọrinti 2:12

    Àwa kò gbà ẹ̀mí ti ayé yìí, bí kò ṣe Ẹ̀mí ẹni tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, kí a lè ní òye ohun tí Ọlọ́run fi fún wa lọ́fẹ̀ẹ́.
    from verse 8
  • 1 Kọrinti 2:13

    Èyí ni àwa ń wí, kì í ṣe èyí tí a ń kọ nípa ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ènìyàn, ṣùgbọ́n èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi ń kọ ènìyàn, èyí tí a ń fi ohun Ẹ̀mí wé ohun Ẹ̀mí.
    from verse 8
  • Mika 3:5

    Báyìí ni Olúwa wí, “Ní ti àwọn Wòlíì tí ń ṣi àwọn ènìyàn mi lọ́nà, tí ẹnìkan bá fún wọn ní oúnjẹ, wọn yóò kéde àlàáfíà; ṣùgbọ́n tí kò bá fi nǹkan sí wọn ní ẹnu, wọn yóò múra ogun sí i.
    from verse 11
  • Jeremiah 26:18

    “Mika ti Moreṣeti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní ọjọ́ Hesekiah ọba Juda. Ó sọ fún gbogbo ènìyàn Juda pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “ ‘A ó sì fa Sioni tu bí oko Jerusalẹmu yóò di òkìtì àlàpà àti òkè ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ibi gíga igbó.’
    from verse 12
  • 1 Kọrinti 2:4

    Ìwàásù mi àti ẹ̀kọ́ mi, kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn àti ọ̀rọ̀ tí a fi ń yí ènìyàn lọ́kàn padà, bí kò ṣe nípa ìfihàn agbára Ẹ̀mí.
    from verse 8
  • Esekiẹli 22:27

    Àwọn ọmọ-aládé àárín rẹ̀ dàbí ìkookò ti ń ṣọdẹ, láti tàjẹ̀ sílẹ̀, láti pa ọkàn run, láti jèrè àìṣòótọ́.
    from verse 2
  • Jeremiah 7:4

    Má ṣe gba ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn gbọ́ kí ẹ sì wí pé, “Èyí ni tẹmpili Olúwa ilé tẹmpili Olúwa, ilé tẹmpili Olúwa!”
    from verse 11
  • Saamu 14:4

    Ǹjẹ́ olùṣe búburú kò ha ní ìmọ̀? Àwọn tí ó ń pa ènìyàn mi jẹ bí ẹní jẹun; wọn kò sì ké pe Olúwa?
    from verse 3
  • Isaiah 1:15

    Nígbà tí ẹ bá tẹ́ ọwọ́ yín sókè ni àdúrà, Èmi yóò fi ojú mi pamọ́ fún un yín, kódà bí ẹ bá gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà, Èmi kò ni tẹ́tí sí i. “Ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀.
    from verse 4
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options