Marku 14:37-40
37
Nígbà tí ó sì padà dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́ta, ó bá wọn lójú oorun. Ó sì wí fún Peteru pé, “Simoni, o ń sùn ni? Ìwọ kò lè bá mi ṣọ́nà fún wákàtí kan?
38
Ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà, ki ẹ má ba à bọ́ sínú ìdánwò. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ‘Ẹ̀mí ń fẹ́ ṣùgbọ́n ó ṣe àìlera fún ara.’ ”
39
Ó sì tún lọ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó sì gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti gbà á ti ìṣáájú.
40
Nígbà tí ó sì tún padà dé, ó bá wọn wọ́n ń sùn, nítorí pé ojú wọn kún fún oorun. Wọn kò sì mọ irú èsì tí wọn ìbá fún un.
Settings