Skip to content
Lefitiku 7:1

Lefitiku 7:1

Ń ṣàfihàn ẹsẹ 1 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
1
“ ‘Wọ̀nyí ni àwọn ìlànà fún rírú ẹbọ ẹ̀bi, tí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ.
2
Níbi tí wọn ti ń pa ẹran ẹbọ sísun ni kí ẹ ti pa ẹran ẹbọ ẹ̀bi, kí ẹ sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí pẹpẹ náà ká.
3
Gbogbo ọ̀rá rẹ̀ ni kí ẹ sun, ọ̀rá ìrù rẹ̀ àti ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú rẹ̀.
4
Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lẹ́bàá ìhà rẹ̀, àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí ó yọ ọ́ pẹ̀lú àwọn kíndìnrín.
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 90 chars

Options