Lefitiku 4:16-21
16
Kí àlùfáà tí a fi òróró yàn sì mú díẹ̀ lára ẹ̀jẹ̀ akọ ọmọ màlúù náà wá sínú àgọ́ ìpàdé.
17
Kí ó ti ìka rẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà kí ó sì wọn ní ẹ̀ẹ̀méje níwájú Olúwa níbi aṣọ títa ẹnu-ọ̀nà.
18
Kí ó sì mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ náà sórí ìwo pẹpẹ tó wà níwájú Olúwa nínú àgọ́ ìpàdé. Ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà ni kí ó dà sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ ẹbọ sísun ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.
19
Kí ó yọ gbogbo ọ̀rá kúrò lára rẹ̀, kí ó sì sun ún lórí pẹpẹ.
20
Kí ó sì ṣe akọ ọmọ màlúù yìí gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ṣe akọ màlúù tó wà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ṣe ètùtù fún wọn, á ó sì dáríjì wọ́n.
21
Lẹ́yìn náà ni yóò sun màlúù yìí lẹ́yìn ibùdó, yóò sì sun ún gẹ́gẹ́ bó ṣe sun màlúù àkọ́kọ́. Èyí ni ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli.
Settings