Lefitiku 19:26-31
26
“ ‘Ẹ má ṣe jẹ ẹrankẹ́ran pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. “ ‘Ẹ kò gbọdọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ yẹ̀míwò tàbí oṣó.
27
“ ‘Ẹ má ṣe dá òṣù sí àárín orí yín (fífá irun ẹ̀gbẹ́ orí, tí a ó sì dá irun àárín orí sí) tàbí kí ẹ ré orí irùngbọ̀n yín bí àwọn aláìkọlà ti ń ṣe.
28
“ ‘Ẹ má ṣe tìtorí òkú, gé ibi kankan nínú ẹ̀yà ara yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ sín gbẹ́rẹ́ kankan. Èmi ni Olúwa.
29
“ ‘Ẹ má ṣe ba ọmọbìnrin yín jẹ́ láti sọ ọ́ di panṣágà, kí ilẹ̀ yín má ba à di ti àgbèrè, kí ó sì kún fún ìwà búburú.
30
“ ‘Ẹ gbọdọ̀ máa pa ìsinmi mi mọ́ kí ẹ sì fi ọ̀wọ̀ fún ibi mímọ́ mi. Èmi ni Olúwa.
31
“ ‘Ẹ má ṣe tọ abókùúsọ̀rọ̀ tàbí àwọn àjẹ́ lọ, ẹ kò gbọdọ̀ tọ̀ wọ́n lẹ́yìn láti jẹ́ kí wọ́n sọ yín di aláìmọ́. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.
Settings